1 Corinthians 2:7-10

7 aBẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. 8 bÈyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. 9 cGẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Ojú kò tí ì rí,
etí kò tí í gbọ́,
kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀
ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.”
10 dṢùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀.

Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ.
Copyright information for YorBMYO